Wednesday, May 6, 2020

OKAN MI YIN OBA ORUN


 1. Okan mi, yin Oba orun,
 Mu ore wa s’odo Re;
 ’Wo t’a wosan t’a dariji,
 Tal’ a ba ha yin bi Re?
 Yin Oluwa, yin Oluwa,
 Yin Oba ainipekun.

2. Yin, fun anu t’O ti fihan,
 F’awon baba ’nu ponju;
 Yin I, okan na ni titi,
 O lora lati binu:
 Yin Oluwa, yin Oluwa,
 Ologo n’nu otito.

3. Bi baba ni O ntoju wa,
 O si mo ailera wa;
 Jeje l’o ngbe wa l’ apa Re,
 O gba wa lowo ota;
 Yin Oluwa, yin Oluwa,
 Anu re yi aiye ka.

4. A ngba b’ itana eweko,
 T’ afefe nfe, t’o si nro;
 ’Gbati a nwa, ti a si nku,
 Olorun wa bakanna;
 Yin Oluwa, yin Oluwa,
 Oba alainipekun.

5. Angel, e jumo ba wa bo,
 Enyin nri lojukoju;
 Orun, osupa, e wole,
 Ati gbogbo agbaiye.
 E ba wa yin, E ba wa yin.
 Olorun Olotito. Amin. 

No comments:

Post a Comment

ONWARD CHRISTIAN SOLDIERS

E-major 1: Onward, Christian soldiers, marching as to war, With the cross of Jesus going on before. Christ, the royal Master, leads against...