1. Jesu l’ Olusagutan mi,
Ore eniti ki ye!
Ko s’ ewu bi mo je Tire,
T’ On si je temi titi.
2. Nib’ odo omi iye nsan,
Nibe l’o nm’ okan mi lo;
Nibiti oko tutu nhu,
L’o nf’ onje orun bo mi.
3. Mo ti fi were sako lo,
N’ ife O si wa miri;
L’ ejika Re l’o gbe mi si,
O f’ ayo mu mi wa ‘le.
4. Nko beru ojiji iku,
B’ Iwo ba wa lodo mi;
Ogo Re ati opa Re,
Awon l’o ntu mi ninu.
5. Iwo te tabili fun mi;
‘Wo d’ ororo sori mi;
A! ayo, na ha ti po to!
Ti nt’ odo Re wa ba mi.
6. Be, lojo aiye mi gbogbo,
Ore re ki o ye lai:
Olusagutan, ngo yin O,
Ninu ile Re titi. Amin.
No comments:
Post a Comment