Wednesday, May 6, 2020

JESU YE TITI AIYE


 1. Jesu ye; titi aiye
 Eru iku ko ba ni mo;
 Jesu ye; Nitorina
 Isa oku ko n’ ipa mo.
 Alleluya!

2. Jesu ye; lat’ oni lo,
 Iku je ona si iye;
 Eyi y’o je ’tunu wa,
 ’Gbat’ akoko iku ba de.
 Alleluya!

3. Jesu ye; fun wa l’ o ku,
 Nje Tire ni a o ma se;
 A o f’ okan funfun sin,
 A o f’ ogo f’ Olugbala.
 Alleluya!

4. Jesu ye; eyi daju,
 Iku at’ ipa okunkun
 Ki y’o le ya ni kuro
 Ninu ife nla ti Jesu.
 Alleluya!

5. Jesu ye; gbogbo ’joba
 L’ orun, li aiye, di Tire;
 E je ki a ma tele,
 Ki a le joba pelu Re.
 Alleluyah! Amin. 


No comments:

Post a Comment

ONWARD CHRISTIAN SOLDIERS

E-major 1: Onward, Christian soldiers, marching as to war, With the cross of Jesus going on before. Christ, the royal Master, leads against...