1. Tire lailai l’ awa se,
Baba, Olorun ife;
Je ka je Tire titi,
Laiye yi, ati lailai.
2. Tire lailai l’ awa se,
Ma toju wa l’ aiye yi:
‘Wo ie, ona, oto,
To wa si ilu orun.
3. Tire lailai:- Abukun
L’ awon t’ o se ‘simi won!
Olugbala, Ore wa,
Gba ‘ja wa ja de opin.
4. Tire lailai:- Jesu, pa
Awon agutan Re mo,
Labo iso rere Re
Ni k’o pa gbogbo wa mo.
5. Tire lailai:- Aini wa
Ni o je aniyan Re;
O ti f’ ese wa ji wa,
To wa si ibugbe Re. Amin.
No comments:
Post a Comment