1. Jesu, nigba’ danwo,
Gbadura fun mi;
K’emi ma ba se O,
Ki nsi sako lo:
’Gba mba nsiyemeji,
K’o bojuwo mi;
K’eru tab’ isaju,
Ma mu mi subu.
2. B’aiye ba si nfa mi,
Pelu adun re;
T’ohun ’sura aiye
Fe han mi l’emo:
Jo mu Getsemane
Wa s’ iranti mi,
Tabi irora Re,
L’oke Kalfari.
3. B’o bap on mi l’oju,
Ninu ife Re;
Da ibukun Re le,
Ori ebo na:
Ki nf’ara mi fun O,
Lori pepe Re;
B’ara ko ago na,
Igbagbo y’o mu.
4. ’Gba mo ban re boji,
Sinu ekuru;
T’ ogo orun si nko,
L’eti bebe na;
Ngo gbekel’ oto Re,
N’ ijakadi ’ku,
Oluwa, gb’emi mi,
S’iye ailopin. Amin.
No comments:
Post a Comment