Wednesday, May 6, 2020

JESU Y'O JOBA NI GBOGBO


 1. Jesu y’o joba ni gbogbo
 Ibit’ a ba le ri orun;
 ’Joba Re y’o tan kakiri,
 ’Joba Re ki o nipekun.

2. On l’ao ma gbadura si,
 Awon oba y’o pe l’Oba;
 Oruko Re b’orun didun,
 Y’o ba ebo oro goke.

3. Gbogbo oniruru ede,
 Y’o fi ’fe Re korin didun:
 Awon omode o jewo
 Pe, ’bukun won t’odo Re wa.

4. ’Bukun po nibit’ On joba:
 A tu awon onde sile;
 Awon alare ri ’simi:
 Alaini si ri ’bukun gba.

5. Ki gbogbo eda k’o dide,
 Kin won f’ola fun Oba wa:
 K’ Angel tun wa t’awon t’orin,
 Ki gbogb’ aiye jumo gberin. Amin. 


No comments:

Post a Comment

ONWARD CHRISTIAN SOLDIERS

E-major 1: Onward, Christian soldiers, marching as to war, With the cross of Jesus going on before. Christ, the royal Master, leads against...