1. Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O;
B’ o tile se ponju,
L’ o mu mi wa;
Sibe, orin mi je,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O.
2. Ni ona ajo mi,
B’ ile ba su,
Bi okuta si je
Irori mi;
Sibe, nin’ ala mi,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O.
3. Nibe je ki nr’ona
T’ o lo s’ orun;
Gbogb’ ohun t’ o fun mi
Nin’ anu Re;
Angeli lati pe mi
Sunm’ O, Olorun mi,
Ngo sunmo O.
4. Nje gbati mo ba ji,
Em’ o yin O:
Ngo f’ akete mi se,
Betel fun O;
Be ninu osi mi,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O.
5. ‘Gba mba fi ayo lo
S’ oke orun,
T’ o ga ju orun lo,
Soke giga:
Orin mi yio je,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O. Amin.
No comments:
Post a Comment