Wednesday, May 6, 2020

WA BA MI GBE

 
 1. Wa ba mi gbe ! ale fere le tan,
 Okunkun nsu; Oluwa ba mi gbe,
 Bi oluranlowo miran ba ye,
 Iranwo alaini, wa ba mi gbe !

2. Ojo aiye mi nsare lo s’opin,
 Ayo aiye nku, ogo re nwomi;
 Ayida at’ ibaje ni mo nri;
 ’Wo ti ki yipada wa ba mi gbe.

3. Ma wa l’ eru b’ Oba awon oba,
 Sugbon ki o ma bo b’oninure;
 Ki o si ma kanu fun egbe mi;
 Wa, Ore elese, wa ba mi gbe !

4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo:
 Ki l’ o le segun Esu b’ ore Re?
 Tal’ o le se amona mi bi Re?
 N’nu ’banuje at’ ayo, ba mi gbe !

5. Pelu’ bukun Re, eru ko ba mi:
 Ibi ko wuwo, ekun ko koro;
 Oro iku da? ’segun isa da?
 Ngo segun sibe, b’ Iwo ba mi gbe.

6. Wa ba mi gbe ni wakati iku,
 Se ’mole mi, si toka si orun:
 B’ aiye ti nkoja, k’ile orun mo,
 Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe. Amin. 


No comments:

Post a Comment

ONWARD CHRISTIAN SOLDIERS

E-major 1: Onward, Christian soldiers, marching as to war, With the cross of Jesus going on before. Christ, the royal Master, leads against...