Friday, May 1, 2020

NINU GBOGBO IJI TI NJA

NINU GBOGBO IJI TI NJA

NINU gbogbo iji ti nja,
Ninu  gbogbo igbi 'ponju,
Abo kan mbe ti o daju,
O wa labe ite-anu

Ibi kan wa ti Jesu nda
Ororo ayo s' ori wa;
O dun ju ibi gbogbo lo,
Ite-anu t'a f' eje won.

Ibi kan wa fun idapo,
Nibi ore npade ore;
Lairi 'ra, nipa igbagbo
Nwon y' ite-anu kanna ka.


A! b' idi l' a o fo sibe,
O dabi aiye ko si mo,
Orun wa 'pade okan wa,
Ogo sib o ite-anu.

No comments:

Post a Comment

ONWARD CHRISTIAN SOLDIERS

E-major 1: Onward, Christian soldiers, marching as to war, With the cross of Jesus going on before. Christ, the royal Master, leads against...